Ẹkisodu 12:38-50 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Ọpọlọpọ àwọn mìíràn ni wọ́n bá wọn lọ, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo aguntan ati agbo mààlúù.

39. Wọ́n mú ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n fi ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, nítorí pé lílé ni àwọn ará Ijipti lé wọn jáde, wọn kò sì lè dúró mú oúnjẹ mìíràn lọ́wọ́.

40. Àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ijipti jẹ́ irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430).

41. Ọjọ́ tí ó pé irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) gééré, tí wọ́n ti dé ilẹ̀ Ijipti; ni àwọn eniyan OLUWA jáde kúrò níbẹ̀.

42. Ṣíṣọ́ ni OLUWA ń ṣọ́ wọn ní gbogbo òru ọjọ́ náà títí ó fi kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn eniyan Israẹli ya alẹ́ ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, láti ìrandíran wọn. Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣọ́nà ní òru ní ìrántí òru àyájọ́ ọjọ́ náà.

43. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Òfin àjọ ìrékọjá nìwọ̀nyí: àlejò kankan kò gbọdọ̀ ba yín jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá.

44. Ṣugbọn àwọn ẹrú tí ẹ fi owó rà, tí ẹ sì kọ ní ilà abẹ́ lè bá yín jẹ ẹ́.

45. Àlejò kankan tabi alágbàṣe kò gbọdọ̀ ba yín jẹ ẹ́.

46. Ilé tí ẹ bá ti se oúnjẹ yìí ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ gbogbo rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ mú ninu ẹran rẹ̀ jáde, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ egungun rẹ̀.

47. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe ìrántí ọjọ́ yìí.

48. Bí àlejò kan bá wọ̀ sí ilé yín, tí ó bá sì fẹ́ bá yín ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá, ó gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé rẹ̀ ní ilà abẹ́, lẹ́yìn náà, ó lè ba yín ṣe àjọ̀dún náà, òun náà yóo dàbí olùgbé ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí kò bá kọ ilà abẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àjọ ìrékọjá náà.

49. Ati ẹ̀yin, ati àlejò tí ń gbé ààrin yín, òfin kan ṣoṣo ni ó de gbogbo yín.”

50. Gbogbo àwọn eniyan Israẹli bá ṣe bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose ati Aaroni.

Ẹkisodu 12