1. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni ní ilẹ̀ Ijipti pé,
2. “Oṣù yìí ni yóo jẹ́ oṣù kinni ọdún fún yín.
3. Ẹ sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù yìí, ọkunrin kọ̀ọ̀kan ninu ìdílé kọ̀ọ̀kan yóo mú ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan tabi àwọ́nsìn kọ̀ọ̀kan; ọ̀dọ́ aguntan kan fún ilé kan.
4. Bí ìdílé kan bá wà tí ó kéré jù láti jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan kan tán, ìdílé yìí yóo darapọ̀ mọ́ ìdílé mìíràn ní àdúgbò rẹ̀, wọn yóo sì pín ẹran tí wọ́n bá pa gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí ó wà ninu ìdílé mejeeji, iye eniyan tí ó bá lè jẹ àgbò kan tán ni yóo darapọ̀ láti pín ọ̀dọ́ aguntan náà.
5. Ọ̀dọ́ aguntan tabi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà kò gbọdọ̀ lábàwọ́n, ó lè jẹ́ àgbò tabi òbúkọ ọlọ́dún kan.
6. Wọ́n óo so ẹran wọn mọ́lẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí. Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli yóo pa ẹran wọn.
7. Wọn yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóo fi kun àtẹ́rígbà ati ara òpó ìlẹ̀kùn mejeeji ilé tí wọn yóo ti jẹ ẹran náà.
8. Alẹ́ ọjọ́ náà ni kí wọ́n sun ẹran náà, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati ewébẹ̀ tí ó korò bí ewúro.
9. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ẹran yìí ní tútù, tabi bíbọ̀; sísun ni kí ẹ sun ún; ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ati àwọn nǹkan inú rẹ̀.
10. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ohunkohun bá ṣẹ́kù, ẹ dáná sun ún.
11. Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí: ẹ di àmùrè yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín, ẹ wọ bàtà yín, ẹ mú ọ̀pá yín lọ́wọ́; ìkánjú ni kí ẹ fi jẹ ẹ́, nítorí pé oúnjẹ ìrékọjá fún OLUWA ni.
12. “Nítorí pé, ní òru ọjọ́ náà ni n óo la gbogbo ilẹ̀ Ijipti kọjá, n óo pa gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ náà, ati ti eniyan ati ti ẹranko, n óo sì jẹ gbogbo àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti níyà. Èmi ni OLUWA.
13. Ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá fi kun àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn gbogbo ilé yín ni yóo jẹ́ àmì láti fi gbogbo ibi tí ẹ bá wà hàn. Nígbà tí mo bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, n óo re yín kọjá; n kò ní fi àjàkálẹ̀ àrùn ba yín jà láti pa yín run nígbà tí mo bá ń jẹ àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti níyà.