Ẹkisodu 1:12-15 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ṣugbọn bí wọ́n ti ń da àwọn ọmọ Israẹli láàmú tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí ba àwọn ará Ijipti.

13. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ àṣekára ni àwọn ọmọ Israẹli lára,

14. wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí wọn pẹlu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ líle. Wọ́n ń po yẹ̀ẹ̀pẹ̀, wọ́n ń mọ bíríkì, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu oko. Pẹlu ìnira ni wọ́n sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe.

15. Nígbà tí ó yá, ọba Ijipti pe àwọn obinrin Heberu tí wọ́n ń gbẹ̀bí, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifira ati Pua, ó sọ fún wọn pé,

Ẹkisodu 1