2. Àwọn eniyan náà pọ̀, wọ́n ṣígbọnlẹ̀. Àwọn òmìrán tíí ṣe ìran Anakimu ni wọ́n. Àwọn tí ẹ ti mọ̀, tí ẹ sì ti ń gbọ́ nípa wọn pé, ‘Ta ni ó lè dúró níwájú àwọn ìran Anaki?’
3. Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.
4. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá lé wọn jáde fun yín, ẹ má ṣe wí ninu ọkàn yín pé, ‘Nítorí òdodo wa ni OLUWA ṣe mú wa wá láti gba ilẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jáde fún wa.’