17. “Bí ẹ bá rò ní ọkàn yín pé àwọn eniyan wọnyi pọ̀ jù yín lọ, ati pé báwo ni ẹ ṣe lè lé wọn jáde,
18. ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Farao ati gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.
19. Ẹ ranti àwọn àrùn burúkú tí ẹ fi ojú ara yín rí, àwọn àmì ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ agbára tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe kí ó tó kó yín jáde. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe sí gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.
20. OLUWA Ọlọrun yín yóo rán agbọ́n sí wọn títí tí gbogbo àwọn tí wọ́n bá farapamọ́ fun yín yóo fi parun.
21. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín, nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín.
22. Díẹ̀díẹ̀ ni Ọlọrun yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí lọ. Kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ẹ óo pa gbogbo wọn run, kí àwọn ẹranko burúkú má baà pọ̀ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ju agbára yín lọ.