Diutaronomi 33:21-26 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn,nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà,ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà,àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́,wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.”

22. Ó súre fun ẹ̀yà Dani pé:“Dani dàbí ẹgbọ̀rọ̀ kinniun, tí ó fò jáde láti Baṣani.”

23. Ó súre fún ẹ̀yà Nafutali pé:“OLUWA ti ṣíjú rere wo Nafutali,ó sì ti bukun un lọpọlọpọ,ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti adágún Galili,títí lọ kan gúsù gbọ̀ngbọ̀n.”

24. Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Aṣeri ni pé:“Ibukun ẹ̀yà Aṣeri ta gbogbo ibukun ẹ̀yà yòókù yọ,àyànfẹ́ ni yóo jẹ́ láàrin àwọn arakunrin rẹ̀,ilẹ̀ rẹ̀ yóo sì kún fún òróró olifi.

25. Ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóo jẹ́ irin ati idẹ,bí iye ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóo pọ̀ tó.”

26. Ẹ̀yin ará Jeṣuruni,kò sí ẹni tí ó dàbí Ọlọrun yín,tí ó gun awọsanma lẹ́ṣin ninu ọlá ńlá rẹ̀,láti wá ràn yín lọ́wọ́.

Diutaronomi 33