61. Àwọn àìsàn mìíràn ati ìpọ́njú tí wọn kò kọ sinu ìwé òfin yìí ni OLUWA yóo dà bò yín títí tí ẹ óo fi parun.
62. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹ kò ni kù ju díẹ̀ lọ mọ́, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín.
63. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ dídùn inú OLUWA láti ṣe yín ní rere ati láti sọ yín di pupọ, bákan náà ni yóo jẹ́ dídùn inú rẹ̀ láti ba yín kanlẹ̀ kí ó sì pa yín run. OLUWA yóo le yín kúrò lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.
64. OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí.