Diutaronomi 28:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. OLUWA yóo fi àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ ṣe ọ́, ati ibà, ìgbóná ati ooru; yóo sì rán ọ̀gbẹlẹ̀, ọ̀dá, ati ìrẹ̀dànù sí ohun ọ̀gbìn rẹ, títí tí o óo fi parun.

23. Òjò kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.

24. Dípò òjò, eruku ni yóo máa dà bò ọ́ láti ojú ọ̀run, títí tí o óo fi parun patapata.

25. “OLUWA yóo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ ṣẹgun rẹ. Bí o bá jáde sí wọn ní ọ̀nà kan, OLUWA yóo tú ọ ká níwájú wọn. Ọ̀rọ̀ rẹ yóo sì di ìyanu ati ẹ̀rù ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.

26. Òkú rẹ yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko tí ń káàkiri orí ilẹ̀ ayé, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí óo lé wọn kúrò.

27. OLUWA yóo da irú oówo tí ó fi bá àwọn ará Ijipti jà bò ọ́, ati egbò, èkúkú ati ẹ̀yi, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wòsàn.

28. OLUWA yóo da wèrè, ìfọ́jú, ati ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bò ọ́.

29. O óo máa táràrà lọ́sàn-án gangan bí afọ́jú. Kò ní dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọn yóo máa ni ọ́ lára, wọn yóo sì máa jà ọ́ lólè nígbà gbogbo; kò sì ní sí ẹnìkan láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

30. “O óo fẹ́ iyawo sọ́nà, ẹlòmíràn ni yóo máa bá a lòpọ̀. O óo kọ́ ilé, o kò sì ní gbé inú rẹ̀. O óo gbin ọgbà àjàrà, o kò sì ní jẹ ninu èso rẹ̀.

31. Wọn óo máa pa akọ mààlúù rẹ lójú rẹ, o kò ní fẹnu kàn ninu rẹ̀. Wọn óo fi tipátipá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lọ lójú rẹ, wọn kò sì ní dá a pada fún ọ mọ́. Àwọn aguntan yín yóo di ti àwọn ọ̀tá yín, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn yín lọ́wọ́.

Diutaronomi 28