Diutaronomi 27:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

17. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹ ààlà ilẹ̀ ẹnìkejì rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

18. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣi afọ́jú lọ́nà.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

19. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹni tí ó bá yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò po, tabi ti aláìní baba, tabi ti opó.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

20. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

21. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo dáhùn pé, ‘Amin.’

22. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ tabi ọmọ baba rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

23. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ìyá aya rẹ̀ lòpọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

Diutaronomi 27