Diutaronomi 27:15-20 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yá ère gbígbẹ́ tabi ère tí wọ́n fi irin rọ. Ohun ìríra ni lójú OLUWA, pé kí àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà fi ọwọ́ gbẹ́ nǹkan, kí ẹnìkan wá gbé e kalẹ̀ níkọ̀kọ̀, kí ó máa bọ ọ́.’“Gbogbo àwọn eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

16. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

17. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹ ààlà ilẹ̀ ẹnìkejì rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

18. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣi afọ́jú lọ́nà.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

19. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹni tí ó bá yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò po, tabi ti aláìní baba, tabi ti opó.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

20. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

Diutaronomi 27