Diutaronomi 24:16-22 BIBELI MIMỌ (BM)

16. “Ẹ kò gbọdọ̀ pa baba dípò ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ pa ọmọ dípò baba, olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá dá.

17. “Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò tabi aláìníbaba po, bẹ́ẹ̀ sì ni, tí ẹ bá yá opó ní ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba aṣọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.

18. Ṣugbọn ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada níbẹ̀, nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí.

19. “Nígbà tí ẹ bá ń kórè ọkà ninu oko yín, tí ẹ bá gbàgbé ìdì ọkà kan sinu oko, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ gbé e. Ẹ fi sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín.

20. Bí ẹ bá ti ká èso olifi yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó.

21. Bí ẹ bá ti ká èso àjàrà yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn opó ati àwọn aláìní baba.

22. Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí.

Diutaronomi 24