15. “Kí baba ati ìyá ọmọbinrin yìí mú aṣọ ìbálé rẹ̀ jáde, kí wọ́n sì mú un tọ àwọn àgbààgbà ìlú náà lọ ní ẹnubodè.
16. Kí baba ọmọ náà wí fún wọn pé, ‘Mo fi ọmọbinrin mi yìí fún ọkunrin yìí ní aya, lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀ tán,
17. ó fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ìṣekúṣe. Ó ní, “N kò bá ọmọ rẹ nílé.” ’ Kí baba ọmọbinrin tẹ́ aṣọ ìbálé rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn àgbààgbà, kí ó sì wí pé, ‘Èyí ni ẹ̀rí pé ó bá ọmọ mi nílé.’
18. Àwọn àgbààgbà ìlú náà yóo mú ọkunrin yìí, wọn yóo nà án dáradára.
19. Wọn yóo sì gba ọgọrun-un ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ́wọ́ rẹ̀ fún baba ọmọbinrin náà bíi owó ìtanràn; nítorí pé ó ti bá ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Israẹli lórúkọ jẹ́. Obinrin náà yóo sì tún jẹ́ iyawo rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
20. “Ṣugbọn bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan obinrin náà bá jẹ́ òtítọ́, pé wọn kò bá a nílé,
21. Wọn yóo fa obinrin náà lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀, àwọn ọkunrin ìlú yóo sì sọ ọ́ ní òkúta pa, nítorí pé ó ti hu ìwà òmùgọ̀ ní Israẹli níti pé ó ṣe àgbèrè ní ilé baba rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.