17. ati ẹyẹ òfù, ati àkàlà, ati ẹyẹ ìgo,
18. ati ẹyẹ àkọ̀, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ òòdẹ̀, ati ẹyẹ atọ́ka, ati àdán.
19. “Gbogbo àwọn kòkòrò tí wọn ń fò jẹ́ aláìmọ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.
20. Ṣugbọn ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní ìyẹ́, tí wọ́n sì mọ́.
21. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀, ẹ lè fún àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín, kí ó jẹ ẹ́, tabi kí ẹ tà á fún àjèjì, nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ ẹni mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun yín.“Ẹ kò gbọdọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ ninu wàrà ọmú ìyá rẹ̀.