Diutaronomi 14:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ọmọ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara yín lára tabi kí ẹ fá irun yín níwájú nígbà tí ẹ bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tí ó kú.

2. Nítorí pé, ẹni ìyàsọ́tọ̀ ni yín fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA ti yàn yín láti jẹ́ eniyan tirẹ̀ láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé.

Diutaronomi 14