Diutaronomi 13:17-18 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Àwọn ìkógun yìí jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu wọn kí OLUWA lè yí ibinu gbígbóná rẹ̀ pada, kí ó ṣàánú fun yín, kí ó sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín.

18. Ẹ máa gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín.

Diutaronomi 13