Diutaronomi 12:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Àwọn ìlànà ati òfin, tí ẹ óo máa tẹ̀lé lẹ́sẹẹsẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fi fun yín láti gbà, nìyí:

2. Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo lé kúrò ti ń sin oriṣa wọn ni kí ẹ wó lulẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà lórí òkè ńlá, ati àwọn tí wọ̀n wà lórí àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ igi tútù.

3. Ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ fọ́ gbogbo òpó wọn, ẹ dáná sun àwọn ère oriṣa Aṣera wọn, ẹ gé gbogbo àwọn ère oriṣa wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò níbẹ̀.

4. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa sin OLUWA Ọlọrun yín káàkiri bí wọ́n ti ń ṣe.

Diutaronomi 12