42. Yóo gbógun ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, Ijipti pàápàá kò ní lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
43. Yóo di aláṣẹ lórí wúrà, fadaka ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ilẹ̀ Ijipti; àwọn ará Libia ati Etiopia yóo máa tẹ̀lé e lẹ́yìn.
44. Ṣugbọn ìròyìn kan yóo dé láti ìlà oòrùn ati àríwá tí yóo bà á lẹ́rù, yóo sì fi ibinu jáde lọ kọlu ọpọlọpọ, yóo sì pa wọ́n run.
45. Yóo kọ́ ààfin ńlá fún ara rẹ̀ ní ààrin òkun ati ní òkè mímọ́ ológo; sibẹ yóo ṣègbé, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn án lọ́wọ́.”