1. Ní ọdún kẹta ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, Nebukadinesari ọba Babiloni wá gbógun ti Jerusalẹmu, ó sì dótì í.
2. OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀.
3. Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli,
4. kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea.