Àwọn Ọba Kinni 8:54-62 BIBELI MIMỌ (BM)

54. Nígbà ti Solomoni parí adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí OLUWA, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì gbé ọwọ́ sókè.

55. Ó dìde dúró, ó sì súre fún gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ó gbadura sókè pé,

56. “Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ.

57. Kí OLUWA Ọlọrun wa kí ó wà pẹlu wa, bí ó ti wà pẹlu àwọn baba ńlá wa; kí ó má fi wá sílẹ̀, kí ó má sì kọ̀ wá sílẹ̀,

58. kí ó ṣe wá ní ẹni tí yóo gbọ́ràn sí òun lẹ́nu, kí á lè máa tọ ọ̀nà rẹ̀, kí á lè máa pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ tí ó fi fún àwọn baba ńlá wa mọ́.

59. Kí OLUWA Ọlọrun wa ranti adura mi yìí ati gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí mo bẹ̀ níwájú rẹ̀ yìí tọ̀sán-tòru, kí ó máa ti èmi iranṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà gbogbo, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀ pẹlu; máa tì wá lẹ́yìn bí ó bá ti tọ́ lojoojumọ,

60. kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé OLUWA ni Ọlọrun, ati pé kò sí ẹlòmíràn mọ́.

61. Ẹ fi tọkàntọkàn jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ẹ tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, kí ẹ sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ bí ẹ ti ń ṣe lónìí.”

62. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ati gbogbo àwọn eniyan rú ẹbọ sí OLUWA.

Àwọn Ọba Kinni 8