15. Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA.
16. Kinní kan ni mo wá fẹ́ tọrọ, jọ̀wọ́, má fi kinní ọ̀hún dù mí.”Batiṣeba bá bi í pé, “Kí ni nǹkan náà?”
17. Ó bá dá Batiṣeba lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi bẹ Solomoni ọba, kí ó fún mi ní Abiṣagi, ará Ṣunemu, kí n fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní kọ̀ sí ọ lẹ́nu.”
18. Batiṣeba bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọba sọ̀rọ̀.”
19. Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀.