14. Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”
15. OLUWA dá a lóhùn pé, “Pada lọ sinu aṣálẹ̀ ẹ̀bá Damasku. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, fi àmì òróró yan Hasaeli ní ọba Siria.
16. Yan Jehu, ọmọ Nimṣi, ní ọba Israẹli, kí o sì yan Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ará Abeli Mehola, ní wolii dípò ara rẹ.
17. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ lọ́wọ́ idà Hasaeli, Jehu ni yóo pa á, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì bọ́ lọ́wọ́ idà Jehu, Eliṣa ni yóo pa á.
18. Sibẹsibẹ n óo dá ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan sí, ní ilẹ̀ Israẹli: àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí mi, tí wọn kò tíì kúnlẹ̀ fún oriṣa Baali, tabi kí wọ́n fi ẹnu wọn kò ó lẹ́nu.”
19. Nígbà tí ó yá, Elija bá kúrò níbẹ̀, bí ó ti ń lọ ó bá Eliṣa ọmọ Ṣafati níbi tí ó tí ń fi àjàgà mààlúù mejila kọ ilẹ̀. Àjàgà mààlúù mọkanla wà níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń kọ ilẹ̀ lọ. Òun alára wà pẹlu àjàgà mààlúù tí ó kẹ́yìn, ó ń fi í kọ ilẹ̀. Elija kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó gbé e wọ Eliṣa.
20. Eliṣa fi àjàgà mààlúù rẹ̀ sílẹ̀, ó sáré tẹ̀lé Elija, o wí fún un pé, “Jẹ́ kí n lọ dágbére fún baba ati ìyá mi, kí n fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, kí n tó máa tẹ̀lé ọ.”Elija dá a lóhùn pé, “Pada lọ, àbí, kí ni mo ṣe fún ọ?”
21. Eliṣa bá pada lẹ́yìn rẹ̀ sí ibi tí àwọn akọ mààlúù rẹ̀ wà, ó pa wọ́n. Ó fi igi tí ó fi ṣe àjàgà wọn ṣe igi ìdáná, ó bá se ẹran wọn. Ó pín ẹran náà fún àwọn eniyan, wọ́n sì jẹ ẹ́. Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Elija, ó ń tẹ̀lé e, ó sì ń ṣe iranṣẹ fún un.