Àwọn Ọba Kinni 19:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ahabu ọba sọ gbogbo ohun tí Elija ṣe fún Jesebẹli, aya rẹ̀, ati bí ó ti pa gbogbo wolii oriṣa Baali.

2. Jesebẹli bá rán oníṣẹ́ kan sí Elija pẹlu ìbúra pé, “Kí àwọn oriṣa pa mí, bí n kò bá pa ọ́ ní ìwòyí ọ̀la, bí o ti pa àwọn wolii Baali.”

3. Ẹ̀rù ba Elija, ó sì sá fún ikú. Ó lọ sí Beeriṣeba, ní ilẹ̀ Juda.Ó fi iranṣẹ rẹ̀ sibẹ,

4. ṣugbọn òun alára wọ inú ijù lọ ní ìrìn odidi ọjọ́ kan kí ó tó dúró. Ó bá jókòó lábẹ́ ìbòòji igi kan, ó wo ara rẹ̀ bíi kí òun kú. Ó sì gbadura sí OLUWA pé, “OLUWA, ó tó gẹ́ẹ́ báyìí! Kúkú pa mí. Kí ni mo fi sàn ju àwọn baba mi lọ?”

Àwọn Ọba Kinni 19