17. Ó dá ọba lóhùn, ó ní, “Kabiyesi, ìwọ ni o ṣe ìlérí fún èmi iranṣẹbinrin rẹ, tí o sì fi orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ búra pé, Solomoni ọmọ mi ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ.
18. Ṣugbọn Adonija ti fi ara rẹ̀ jọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kabiyesi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.
19. Ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Abiatari alufaa, ati Joabu balogun rẹ síbi àsè rẹ̀, ṣugbọn kò pe Solomoni, iranṣẹ rẹ.
20. Ojú rẹ ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń wò báyìí, pé kí o fa ẹni tí o bá fẹ́ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ kalẹ̀ fún wọn.
21. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbàrà tí kabiyesi bá ti kú tán, bí wọ́n ti ń ṣe àwọn arúfin ni wọn yóo ṣe èmi ati Solomoni ọmọ rẹ.”