27. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.”
28. Obinrin náà bá sọ fún Eliṣa pé, “Ǹjẹ́ mo tọrọ ọmọ lọ́wọ́ rẹ bí? Ǹjẹ́ n kò sọ fún ọ kí o má ṣe tàn mí jẹ?”
29. Eliṣa bá sọ fún Gehasi pé, “Ṣe gírí, kí o mú ọ̀pá mi lọ́wọ́, kí o sì máa lọ. Bí o bá pàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà, má ṣe kí i, bí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má dáhùn.”
30. Nígbà náà ni ìyá ọmọ náà wí pé “Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè tí ẹ̀mí ìwọ pàápàá sì ń bẹ, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Gehasi bá dìde, ó bá a lọ.
31. Ó lọ fi ọ̀pá Eliṣa lé ọmọ náà lójú, ṣugbọn ọmọ náà kò jí. Ó bá pada lọ sọ fún Eliṣa pé ọmọ náà kò jí.
32. Nígbà tí Eliṣa dé ilé náà, ó bá òkú ọmọ náà lórí ibùsùn.
33. Ó wọlé síbi tí òkú ọmọ náà wà, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì gbadura sí OLUWA.
34. Ó nà gbalaja lé ọmọ náà lórí, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó fojú kò ó lójú, ó sì gbé ọwọ́ lé ọwọ́ rẹ̀. Bí ó sì ti nà lé ọmọ náà, ara ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ wọ́ọ́rọ́.