Àwọn Ọba Keji 22:6-12 BIBELI MIMỌ (BM)

6. àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn agbẹ́kùúta, kí wọ́n sì ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe ilé OLUWA.

7. Ó ní àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé náà kò ní nílò láti ṣe ìṣirò owó tí wọn ń ná, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

8. Ṣafani jíṣẹ́ ọba fún Hilikaya; Hilikaya olórí alufaa, sì sọ fún un pé òun ti rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA. Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, ó sì kà á.

9. Ṣafani bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba, ó sọ fún ọba pé, àwọn iranṣẹ rẹ̀ ti kó owó tí ó wà ninu ilé OLUWA fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA,

10. ati pé Hilikaya fún òun ní ìwé kan; ó sì kà á sí etígbọ̀ọ́ ọba.

11. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

12. Ó bá pàṣẹ fún Hilikaya alufaa, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Akibori ọmọ Mikaya, Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba pé,

Àwọn Ọba Keji 22