Àwọn Ọba Keji 21:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ati pé bí àwọn ọmọ Israẹli bá júbà àṣẹ mi, tí wọ́n pa òfin mi, tí Mose, iranṣẹ mi, fún wọn mọ́, n kò ní jẹ́ kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.”

9. Ṣugbọn àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda kò júbà OLUWA, Manase sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú ju èyí tí àwọn eniyan ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ dá lọ, àní, àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

10. OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, pé,

11. “Manase ọba ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, wọ́n burú ju èyí tí àwọn ará Kenaani ṣe lọ. Ó sì mú kí Juda dẹ́ṣẹ̀ nípa pé wọ́n ń bọ àwọn ère rẹ̀.

12. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ìparun wá sórí Jerusalẹmu ati Juda, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́.

13. Ó ní òun óo jẹ Jerusalẹmu níyà bí òun ti jẹ Samaria níyà. Ó ní bí òun ti ṣe sí ìdílé Ahabu ati àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun óo gbá àwọn eniyan náà kúrò ní Jerusalẹmu, bí àwo tí a nù tí a sì da ojú rẹ̀ bolẹ̀.

Àwọn Ọba Keji 21