35. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni angẹli OLUWA lọ sí ibùdó ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an lé ẹẹdẹgbaata (185,000) àwọn ọmọ ogun, wọn kú kí ilẹ̀ ọjọ́ keji tó mọ́.
36. Senakeribu ọba Asiria bá pada sí Ninefe.
37. Ní ọjọ́ kan níbi tí ó ti ń bọ oriṣa ninu ilé Nisiroku, oriṣa rẹ̀, ni Adirameleki ati Ṣareseri, àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi idà pa á, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ bá jọba lẹ́yìn rẹ̀.