2. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀.
3. OLUWA bínú sí Israẹli, ó sì jẹ́ kí Hasaeli, ọba Siria, ati Benhadadi ọmọ rẹ̀ ṣẹgun Israẹli ní ọpọlọpọ ìgbà.
4. Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀.
5. (Nítorí náà, OLUWA rán olùgbàlà kan sí Israẹli láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Siria, ọkàn àwọn eniyan Israẹli sì balẹ̀ bíi ti ìgbà àtijọ́.