Àwọn Ọba Keji 12:19-21 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Gbogbo nǹkan yòókù tí Joaṣi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

20. Àwọn olórí ogun Joaṣi ọba dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ilẹ̀ Milo ní ọ̀nà tí ó lọ sí Sila.

21. Josakari, ọmọ Ṣimeati ati Jehosabadi, ọmọ Ṣomeri, àwọn olórí ogun, ni wọ́n pa á. Wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwọn Ọba Keji 12