18. Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́.
19. Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀.
20. Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀.
21. Àwọn Filistini bá kì í mọ́lẹ̀, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n mú un wá sí ìlú Gasa, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ dè é. Wọ́n ní kí ó máa lọ àgbàdo ninu ilé ẹ̀wọ̀n.