29. Àwọn ọmọ Efuraimu kò lé àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Geseri jáde, wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa gbé ààrin wọn.
30. Àwọn ọmọ Sebuluni kò lé àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Kitironi jáde, ati àwọn tí ó ń gbé Nahalali, ṣugbọn àwọn ará Kenaani ń bá wọn gbé, àwọn ọmọ Sebuluni sì ń fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́.
31. Àwọn ọmọ Aṣeri náà kò lé àwọn wọnyi jáde: àwọn ará Ako ati àwọn ará Sidoni, àwọn ará Ahilabu ati àwọn ará Akisibu, àwọn ará Heliba ati àwọn ará Afeki, ati àwọn ará Rehobu.
32. Ṣugbọn àwọn ọmọ Aṣeri ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani tí wọ́n bá ní ilẹ̀ náà, nítorí pé wọn kò lé wọn jáde.