Àwọn Adájọ́ 1:28-30 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára sí i, wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará Kenaani ṣiṣẹ́, ṣugbọn wọn kò lé wọn kúrò láàrin wọn patapata.

29. Àwọn ọmọ Efuraimu kò lé àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Geseri jáde, wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa gbé ààrin wọn.

30. Àwọn ọmọ Sebuluni kò lé àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Kitironi jáde, ati àwọn tí ó ń gbé Nahalali, ṣugbọn àwọn ará Kenaani ń bá wọn gbé, àwọn ọmọ Sebuluni sì ń fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́.

Àwọn Adájọ́ 1