Amosi 5:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ fetí sí orin arò tí mò ń kọ le yín lórí, ẹ̀yin ìdílé Israẹli:

2. Israẹli, ọdọmọbinrin, ṣubú,kò ní lè dìde mọ́ lae.Ó di ìkọ̀sílẹ̀ ní ilẹ̀ rẹ̀,kò sì sí ẹni tí yóo gbé e dìde.

3. OLUWA Ọlọrun ní: “Ninu ẹgbẹrun ọmọ ogun tí ìlú Israẹli kan bá rán jáde, ọgọrun-un péré ni yóo kù. Ninu ọgọrun-un tí ìlú mìíràn bá rán jáde, mẹ́wàá péré ni yóo kù.”

4. OLUWA ń sọ fún ilé Israẹli pé: “Ẹ wá mi, kí ẹ sì yè;

5. ẹ má lọ sí Bẹtẹli, ẹ má sì wọ Giligali, tabi kí ẹ kọjá lọ sí Beeriṣeba; nítorí a óo kó Giligali lọ sí oko ẹrú, Bẹtẹli yóo sì di asán.”

6. Ẹ wá OLUWA, kí ẹ sì yè; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo rọ̀jò iná sórí ilé Josẹfu, ati sí ìlú Bẹtẹli; kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa á.

Amosi 5