1. OLUWA ní: “Àwọn ará Moabu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n sọná sí egungun ọba Edomu, wọ́n sun ún, ó jóná ráúráú.
2. Nítorí náà, n óo sọ iná sí Moabu, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Kerioti ní àjórun. Ninu ariwo ogun ati ti fèrè ni Moabu yóo parun sí,
3. n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ run.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
4. Ó ní: “Àwọn ará Juda ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n ti kọ òfin èmi OLUWA sílẹ̀, wọn kò sì rìn ní ìlànà mi. Àwọn oriṣa irọ́ tí àwọn baba wọn ń bọ, ti ṣì wọ́n lọ́nà.
5. Nítorí náà, n óo sọ iná sí Juda, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Jerusalẹmu ní àjórun.”
6. OLUWA ní: “Àwọn ará Israẹli ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí pé wọ́n ta olódodo nítorí fadaka, wọ́n sì ta aláìní nítorí bàtà ẹsẹ̀ meji.