4. Nítorí náà, n óo sọ iná sí ààfin Hasaeli, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi kanlẹ̀.
5. N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àwọn ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
6. Ó ní: “Àwọn ará Gasa ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí odidi orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n kó lẹ́rú, tí wọ́n lọ tà fún àwọn ará Edomu.
7. N óo sọ iná sí ìlú Gasa, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.
8. N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.
9. Ó ní: “Àwọn ará Tire ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n kó odidi orílẹ̀-èdè kan lẹ́rú lọ tà fún àwọn ará Edomu. Wọn kò sì ranti majẹmu tí wọ́n bá àwọn arakunrin wọn dá.
10. Nítorí náà n óo sọ iná sí orí odi ìlú Tire, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.”
11. OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn.
12. Nítorí náà, n óo rán iná sí ìlú Temani, yóo sì jó ibi ààbò Bosira ní àjórun.”