Aisaya 54:10-14 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò,tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí,ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ,majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀.Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

11. OLUWA ní:“Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá,tí a kò sì tù ninu,òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ,òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.

12. Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ,òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ,àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ.

13. “Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí.

14. A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo,o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́.O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ.

Aisaya 54