Aisaya 43:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín,Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”

16. OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;

17. ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,wọ́n kú bí iná fìtílà.

18. ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.

19. Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titunó ti yọ jáde nisinsinyii,àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?N óo la ọ̀nà ninu aginjù,n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.

20. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo,ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò;nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀,kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:

21. Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi,kí wọ́n lè kéde ògo mi.

22. “Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

23. Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi,tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi.N kò fi tipátipá mu yín rúbọ,bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá.

Aisaya 43