4. Nígbà tí OLUWA bá ti fọ èérí Jerusalẹmu dànù, tí ó sì jó o níná tí ó sì mú ẹ̀bi ìpànìyàn kúrò níbẹ̀, nípa pé kí wọn máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́,
5. ní ọ̀sán, yóo mú kí ìkùukùu bo gbogbo òkè Sioni ati àwọn tí ó ń péjọ níbẹ̀; ní alẹ́, yóo sì fi èéfín ati ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ bò wọ́n. Ògo OLUWA yóo bò wọ́n bí àtíbàbà ati ìbòrí.
6. Yóo dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ oòrùn lọ́sàn-án, yóo jẹ́ ibi ìsásí ati ààbò fún wọn lọ́wọ́ ìjì ati òjò.