1. Tí ó bá di ìgbà náà, obinrin meje yóo rọ̀ mọ́ ọkunrin kan ṣoṣo, wọn óo máa bẹ̀ ẹ́ pé, “A óo máa bọ́ ara wa, a óo sì máa dá aṣọ sí ara wa lọ́rùn. Ṣá máa jẹ́ ọkọ wa, kí á máa jẹ́ orúkọ rẹ; kí o mú ìtìjú kúrò lọ́rọ̀ wa.”
2. Tí ó bá di ìgbà náà, ẹ̀ka igi OLUWA yóo di ohun ẹwà ati iyì. Èso ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ògo ati àmúyangàn fún àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá kù.