Aisaya 31:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé!Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin;tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀,tí wọ́n gbójú lé ẹṣinnítorí pé wọ́n lágbára!Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli,wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.

2. Bẹ́ẹ̀ ni ó gbọ́n,ó sì mọ ọ̀nà tí ó fi lè mú kí àjálù dé bá eniyan,kì í sọ̀rọ̀ tán, kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada.Ṣugbọn yóo dìde sí ìdílé àwọn aṣebi,ati àwọn tí ń ti àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn.

3. Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti,wọn kìí ṣe Ọlọrun.Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọnwọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú.Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú,ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ,ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú;gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀.

Aisaya 31