26. Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn.
27. Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè,ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú;ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè.Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu;ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run.
28. Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀tí ó lè mu eniyan dé ọrùn.Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè,yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu.
29. Ẹ óo kọ orin kan bí orin alẹ́ ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́,inú yín yóo sì dùn bíi ti ẹni tí ń jó ijó fèrè lọsórí òkè OLUWA, àpáta Israẹli.
30. OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo,yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńláati ninu iná ajónirun;pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín.
31. Ìbẹ̀rù-bojo yóo mú àwọn ará Asirianígbà tí wọ́n bá gbóhùn OLUWA,nígbà tí ó bá fi kùmọ̀ rẹ̀ lù wọ́n.
32. Ìró ọ̀pá tí OLUWA yóo fi nà wọ́n yóo dàbí ìró aro ati dùùrù.OLUWA yóo dojú ogun kọ wọ́n.
33. Nítorí pé a ti pèsè iná ìléru sílẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ fún ọba Asiria;iná ńlá tí ń jó pẹlu ọpọlọpọ igi.Èémí OLUWA tó dàbí ìṣàn imí-ọjọ́ ni yóo ṣá iná sí i.