1. OLUWA ní:“Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé.Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi,tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ,ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi;kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.
2. Wọ́n múra, wọ́n gbọ̀nà Ijiptiláì bèèrè ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi.Wọ́n lọ sápamọ́ sí abẹ́ ààbò Farao,wọ́n lọ wá ààbò ní Ijipti.
3. Nítorí náà, ààbò Farao yóo di ìtìjú fún wọn,ibi ìpamọ́ abẹ́ Ijipti yóo di ìrẹ̀sílẹ̀ fún wọn.
4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí wọn ti lọ sí Soani,tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé Hanesi.
5. Ojú yóo tì wọ́n, nítorí wọn ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́.Wọn kò lè rí ìrànwọ́ tabi anfaani kankan níbẹ̀, bíkòṣe ìtìjú ati ẹ̀gàn.”
6. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí:“Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí.Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá.Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun,ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò.Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani.