Aisaya 29:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀,láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀.A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú,a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀.

5. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn,ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.

6. Lójijì, kíá,OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín,pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá;ati ààjà, ati ìjì líle,ati ahọ́n iná ajónirun.

7. Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà,yóo parẹ́ bí àlá,gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà,tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru.

8. Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun,tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun,tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlápé òun ń mu omiṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun,bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà.

9. Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀,kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀.Ẹ fọ́ ara yín lójúkí ẹ sì di afọ́jú.Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí.Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle.

10. Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín láraÓ ti di ẹ̀yin wolii lójú;ó ti bo orí ẹ̀yin aríran.

11. Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú,bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì.Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wétí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”Ó ní òun kò lè kà ánítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í.

Aisaya 29