10. Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni,èyí òfin, tọ̀hún ìlànà.Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”
11. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lòláti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀.
12. Àwọn tí ó ti wí fún pé:Ìsinmi nìyí,ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi;ìtura nìyí.Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.
13. Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin,èyí òfin tọ̀hún ìlànà.Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún,kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìnkí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́;kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn,kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n.
14. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan,tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu.
15. Nítorí ẹ wí pé:“A ti bá ikú dá majẹmu,a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn.Nígbà tí jamba bá ń bọ̀,kò ní dé ọ̀dọ̀ wa;nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa,a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.”