Aisaya 2:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí:

2. Ní ọjọ́ iwájúòkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ,a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ.Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ.

3. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé:“Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ,kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀,kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wáọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.”

4. Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí.Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.

5. Ẹ̀yin ìdílé Jakọbuẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA.

6. Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù,àní, ìdílé Jakọbu.Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn,àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini,Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì.

Aisaya 2