Aisaya 16:6-9 BIBELI MIMỌ (BM)

6. A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu,bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ:ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀.

7. Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún,kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu.Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi,tí ó ní èso àjàrà ninu.

8. Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni;bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma:àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀,èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀.Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀,wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun.

9. Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibumabí mo ṣe sọkún fún Jaseri;mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale,mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrònítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ.

Aisaya 16