4. Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara,àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn;nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún,ọkàn rẹ̀ sì wárìrì.
5. Ọkàn mi sọkún fún Moabu;àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya.Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ,wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu.
6. Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀,koríko ibẹ̀ gbẹ;àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́.
7. Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọati ohun ìní tí wọn ti kó jọ,ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo.