Sekaráyà 6:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:

10. “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Hélídáì, tí Tóbíyà, àti ti Jédáyà, tí ó ti Bábílónì dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Jósáyà ọmọ Séfánáyà lọ.

11. Kí o sì mú sílifà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà.

12. Sì sọ fún un pé: ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogún sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa wa.

13. Òun ni yóò sì kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jọba lorí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lorí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrin àwọn méjèèje.’

14. Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Hélémù àti fún Tóbíyà, àti fún Jédíà, àti fún Hénì ọmọ Sefanáyà fún irántí ni tẹ́ḿpìlì Olúwa.

Sekaráyà 6