5. Ańgẹ́lì náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé.
6. Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde tẹ̀lé wọn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúsù.”
7. Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn báa lè rìn síhín-sọ́hùnún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-sọ́hùn ní ayé!” Wọ́n sì rín síhìnín-sọ́hùnún ní ayé.
8. Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá.”
9. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:
10. “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Hélídáì, tí Tóbíyà, àti ti Jédáyà, tí ó ti Bábílónì dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Jósáyà ọmọ Séfánáyà lọ.
11. Kí o sì mú sílifà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà.
12. Sì sọ fún un pé: ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogún sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa wa.