1. Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lébánónì,kí iná bá lè jẹ igi Kédárì rẹ run,
2. Pohùnréré-ẹkún, igi fírì;nítorí igi Kédárì ṣubú,nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́:ṣunkún kíkorò ẹ̀yin igi óákù tí Básánì,nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀.
3. Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn;ògo wọn bàjẹ́;gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìúnnítorí ògo Jódánì bàjẹ́.
4. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́-ẹran àbọ́pa.
5. Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn.